HYMN 489

(FE 515)
Tune: “Olorun gbogbo araiye"



1.  OLORUN opo arugbo 

     T’aiye ro pe ko le bimo mo 

     N‘Iwo se l‘ogo to bimo

     O si d’oju t’awon ota re.

Egbe:  Gbo temi, gbo temi

           Gbo temi, Oba awimayehun

           Gbo temi, gbo temi

           Gbo temi, Oba awimayehun.


2.  O s’arugbo di wundia 

     Olorun to la Serah lagan 

     Ko ku, ko sa O wa nibe 

     Baba, se ‘ranlowo wa loni. 

Egbe:  Gbo temi, gbo temi...


3.  Sarah fere ma tun le gba

     Pe'ru on tun le bimo mo

     Lo fi rerin ninu okan 

     Sugbon Olorun ko ka s'ese fun. 

Egbe:  Gbo temi, gbo temi...


4.  Okiki Olorun mi kan 

     Oju mi ko ri ‘ru eyi ri 

     T‘igi t’ope lo ndamuso 

     Fun iloyun Elisabeti. 

Egbe:  Gbo temi, gbo temi...


5.  Hihu agbado ki tase 

     Hihu oka ti tase

     Mase jek‘ arabinrin yi 

     Tase omo rere lodo Re.

Egbe:  Gbo temi, gbo temi...


6,  Baba, Omo, Emi Mimo 

     Ko s’awati ore lodo Re 

     Ma jek‘oso aje dina

     Lati f‘arabinrin yi l‘omo.

Egbe:  Gbo temi, gbo temi

           Gbo temi, Oba awimayehun

           Gbo temi, gbo temi

           Gbo temi, Oba awimayehun. Amin

English »

Update Hymn