HYMN 488

8s 7s
Ma Toju Mi Jihofa Nla



1.  WO awon t'o wo ‘so ala 

     Won duro leti odo

     Won k‘eyin s'aye at‘esu 

     Won ntele Atebomi

     Won si nreti 

     Lati se ase Jesu.


2.  Wo bi won ti duro l'eru 

     Sugbon pelu ireti

     Won mo pe Olugbala won 

     L‘O pase odo lilo

     Jordan tutu

     Sugbon igbagbo gbona.


3.  Si wo awon arakunrin

     Egbon won ninu Jesu

     Wo bi won ti na’ wo ife

     Won sa ti dabi won ri, Nisisiyi 

     Won ny‘ayo idariji.


4.  Lo, tele Olugbala yin 

     E f'oju igbagbo ri

     A! orun si, Emi Baba

     Si nke lat‘oke wipe

     Awon wonyi

     Ni ayanfe omo Mi.  Amin

English »

Update Hymn