HYMN 487

1.  LATI 'nu ide ibanuje

     Jesu mo de, Jesu mo de 

     Mo wa gba omnira at’ayo 

     Jesu mo wa do Re 

     Alaisan, emi nfe iwosan 

     Alaini, so mi di oloro 

     Elese, mo wa si odo Re 

     Jesu, mo wa‘do Re.


2.  Eni-tiju ati eIeya

     Jesu mo de, Jesu mo de 

     Mo wa jere nla n’nu iku Re 

     Jesu mo wa’do Re 

     Wo n'itunu fun ibanuje 

     Wo n‘isimi fun gbogbo iji 

     Jesu mo wa’do Re.


3.  Ninu rudurudu aiye yi 

     Jesu mo de, Jesu mo de 

     Mo wa s'inu pipe ife Re 

     Jesu mo wa’do Re 

     Mu mi kuro n’nu ife ara 

     Kuro ninu aiye asan yi

     Ki nle wa fi’ye idi goke 

     Jesu mo wa’do Re.


4.  N‘nu eru iku at‘iboji

     Jesu mo de, Jesu mo de 

     Mo wa s'inu ayo ile mi 

     Jesu mo wa'do Re

     Lati nu iho iparun nla 

     Sinu alafia t‘o jinle

     Lati wa w‘oju Re ologo 

     Jesu mo wa‘do Re.  Amin

English »

Update Hymn