HYMN 482

S.S. 393 (FE 508)
"Anu nsan pupo, Iwo Oluwa po"
- Ps.86:5



1.  OGO fun Jesu f'anu Re lofe

     Anu lofe, anu lofe,

     Elese anu nsan, fun o lofe

     Anu nsan pupo lofe

     Bi iwo ba fe lati gba a gbo

     Anu lofe, anu lofe 

     Iwo yio r'iye ainipekun gba

     Anu nsan pupo lofe.

Egbe:  Jesu Olugbala nwa o kiri

            Nwa o kiri, nwa o kiri

            T'anu -t'anu t'ife lo fi npe o,

            O npe o, O nwa o kiri.


2.   Ese to nkiri lokiti ese?

      Anu lofe, anu lofe 

      Emi npe o jeje wipe wa 'le

      Anu nsan pupo lofe

      O nwa n'okun bi? A! wa si 'mole

      Anu lofe, anu lofe

      Jesu nduro yio gba o lale yi 

      Anu nsan pupo lofe.

Egbe:  Jesu Olugbala nwa o kiri...


3.   Ro ti ore, suru, ati ife re

      Anu lofe, anu lofe 

      O bebe fun o lodo Baba loke

      Anu nsan pupo lofe

      Wa ronupiwada fun lokan re

      Anu lofe, anu lofe

      Ma banuje sugbon wa b'o ti ri

      Anu nsan pupo lofe.

Egbe:  Jesu Olugbala nwa o kiri...


4.   Nje anu wa fun gbogb' eni gbagbo

      Anu lofe, anu lofe 

     Wa k'o si gba 'bukun nisisiyi

      Anu nsan pupo lofe

      esu nduro, A! gbo b'O ti nkede

      Anu lofe, anu lofe

      Ro mo 'leri Re 'gba Oko Re gbo

      Anu nsan pupo lofe.

Egbe:  Jesu Olugbala nwa o kiri

            Nwa o kiri, nwa o kiri

            T'anu -t'anu t'ife lo fi npe o,

            O npe o, O nwa o kiri.  Amin

English »

Update Hymn