HYMN 48

SS 379 (FE 65)
"E we, ki e mo” - Isa 1:16



1.  OTITO Jesu f ’agbara ‘wenumo 

     A we o ninu eje Odagutan

    Iwo ha gbekele ore-ofe Re,

    A we o ninu eje Odagutan.

Egbe:  Awe o, ninu eje

           Ninu eje Odagutan fun okan

           Asa re ha funfun o si mo laulau 

          Awe o ninu eje Odagutan.


2.  O mba Olugbala rin lojo jumo 

     A we o ninu eje Odagutan

    O simi le Eniti a kan mo’gi

    A we o ninu eje Odagutan.

Egbe:  Awe o, ninu eje...


3.  Aso re funfun lati pade Oluwa, 

     O mo lau ninu eje Odagutan 

     Okan re mura fun ‘le didan loke 

     K’a we o ninu eje Odagutan.

Egbe:  Awe o, ninu eje...


4.  Bo ewu eri ese si apa kan

     Ko si we ninu eje Odagutan 

     Isun kan nsan fun gbogbo okan aimo,

     Jo lo we ninu eje Odagutan.

Egbe:  Awe o, ninu eje...  Amin

English »

Update Hymn