HYMN 479

S.S. & S 417 (FE 505) 
"Jesu Omo Dafidi, sanu fun wa"
 - Matt. 10:4



1.  ANU Re, Oluwa, l‘awa ntoro 

     Ro jo Re le wa

     Eiye ti nfo at’era to nrin ‘le 

     Nri won lopolopo.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re

           Baba wa orun

           L'awa ntoro

           Abiyamo ki gbagbe omo Re 

           Jesu ma gbagbe mi.


2.  Orun l'osan nipa ase Re ni 

     At'osupa l’oru

     Igba ojo at‘igba ikore 

     Lowo re ni nwon wa.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


3.  Gbati esu at’ese ndode wa 

     Ikolu won soro 

     Logo asan arankan ti p’aiya 

     Oluwa gba wa la.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


4.  Dafidi ko le gbagbe anu Re 

     Niwaju Golayat,

     Danieli ‘nu iho Kiniun

     lwo lo ns’abo re.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


5.  lru anu wonyi l'awa ntoro 

     Ro ojo Re le wa
  
     Larin ota je ki awa ma gba 

     Fun iyin ogo Re.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


6.  Anu bi Batimeu afoju 

     L‘a ntoro lodo Re

     Ati gbogbo awon alailera

     Nwonri anu Re gba. 

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


7.  Ayaba Esita ko le gbagbe 

     Lasiko ‘damu Re 

     Adura lo fi segun ota re 

     Olorun lo ja fun.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re...


8.  Ota ile ko le se o nibi 

     Gbeke re le Jesu

     Aje, oso ati alawirin 

     Nwon npete l’asan ni.

Egbe:  Anu, Anu, Anu Re

           Baba wa orun

           L'awa ntoro

           Abiyamo ki gbagbe omo Re 

           Jesu ma gbagbe mi.  Amin

English »

Update Hymn