HYMN 478

(FE 504)
Tune: Jeka layo ninu Jesu
“Emi o fe Oluwa” - Ps. 18:1



1.  OLORUN ‘Wo l’agbara mi 

     Emi o feran re

     Iwo l’odi at’abo mi

     Ni igba aini mi.


2.  Ni gba ‘rora on ‘banuje 

     Mo toro or-ofe

     Olorun gbo aroye mi 

     Lat’ibi mimo Re.


3.  Ati ninu ola‐nla Re 

    O gun awon Kerubu 

     L’apa iye afefe

     L’o si nfo kakiri.


4.  O mu mi sibi titeju 

      Ki nle di omnira

      O si pa mi mo nitori 

      Inu Re dun simi.


5.  Ona Olorun mo pupo 

     Oro Re ye koro

     Awon t’o ntele ona Re 

     Ni abo t’o daju.  Amin

English »

Update Hymn