HYMN 477

(FE 503)
Tune: Jesu mo wa sodo Re



1.  OLUWA  jowo pa wa mo 

     Iwo l’awa gbekele

     Okan wa wi f ’Oluwa pe 

     Iwo li Olorun wa.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin Re Baba 

           Iwo l’awa gbekele 

           Mase fi wa sile f’ota

          K’asegun n’ile l’ode.


2.  S’awon enia mimo Re

     Ani s’awon olola

     Bi eniti didun ‘nu wa

     Yio, ma wa titi lailai.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


3.  Ibinuje awon ti nsa 

     T’Olorun miran yio po 

     Ebo ohun min’eje won 

     L’emi ki yio ta sile.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


4.  Oluwa n’ipin ini mi 

     Ati ipin ago mi

     Sewo lo mu la mi duro

     T’o ko je k’ota ba je.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


5.  Okun tita bo s‘odo mi

     Nibi t’o dara julo

     L‘otito mo fowo soya

     Pe mo ni ogun rere.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


6.  Emi o fi ‘bukun f’Oluwa 

     To fun mi ni imoran 

     Okan mi pelu sa nko mi 

     L’arin wakati oru.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


7.  Mo gb'Oluwa ka ‘waju mi 

     Nibi gbogbo l’aiye mi 

     Tori o wa lowo ‘tun mi

     A ki yio si mi nipo.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


8.  Torina n'nu mi se dun

     T'ogo mi si nyo jade

     Ara mi pelu yio simi

     Ni ‘re ti iye ailopin. 

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


9.  O ki yio f'okan mi sile

     Li arin ipo oku

     Beni eni mimo tire

     Ki yipo idibaje.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


10.  Mo mo p‘o f’ona ‘ye han mi, 

       Waju re l'ekun ayo wa

       Li owo otun Re sa ni

       Didun 'nu mi wa lailai.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


11.  S’alabo Egbe Serafu 

       Ati Egbe Kerubu

       Awon to nsin O nitoto

      Nigun mererin aiye.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin... 


12.  Eje ka f ’ogo fun Baba 

       Ati fun Omo pelu

       Je ka f’ogo f’Emi Mimo

       Metalokan Aiyeraiye.

Egbe:  A ko ni ‘re kan lehin Re Baba 

           Iwo l’awa gbekele 

           Mase fi wa sile f’ota

          K’asegun n’ile l’ode.  Amin

English »

Update Hymn