HYMN 475

H.C 601 8s 7s (FE 501)
“Eniti npa o mo ki yio togbe”
 - Ps. 121:3



1.  LOWO kiniun at’ekun 

     Lowo eranko ibi

     Jo so aw'Egbe Serafu 

     At’om’Egbe kerubu 

     Ninu gbogbo iji to nja 

     A! nibo l'aba sa si

     A! Baba ma fi wa sile 

     Segun Satani fun wa.


2.  Ko s'ona ti a ba tun to 

     To le bori ona yi

     Je ka diju si nkan t’aiye 

     Ka laju si nkan t’orun 

     Maje k'aiye fa wa s'ehin 

     Kuro ninu ona Re

     N’nu banuje at’iponju 

     Emi ki o fi O sile.


3.  Ade ogo yio je ti nyin 

     T'enyin ko ba sin l’etan 

     Mo se tan mo ti pa nyin po 

     Emi ni Emi Airi

     Sugbon mo wa n‘nu Olanla 

     Mo le pa, mo le gbala 

     Je arowa k’e ma w’ehin 

     K'e le gbere nikehin.


4.  lfe to dopin la ntoro

     Fun gbogb' Egbe to papo

     E ja, e segun, e bori

     Laiye yi ati lorun

     Sugbon danwo tun wa l'orun 

     A! bawo ni yio ti ri

     Ka gbo p’o ti je Serafu

     O tun pada nikehin.


5.  Ohun ti mo ba pa lase 

     Ma f 'ogbon ori yipada 

     Eniti ko ba gba ‘ran gbo 

     O dabi eniti O

     Ko ‘le re si eti odo 

     Ekun omi de o gba lo

     K'e mase ro p’agbara nyin 

     La ko se fi nyin sile.


6.  Jesu se tan lati gba nyin

     O kun f’anu at’ife

     Gb’ara re le patapata

     Ma gb’ekelohun miran 

     Ghohun-gbohun oruko Re 

     Si gba gbogbo orun kan 

     Ke Halleluya s‘Olorun

     Fi 'barale juba Re.


7.  E f’Ogo fun Baba loke

     E f’Ogo fun Omo Re 

     Metalokan aiyeraiye

     A juba Oruko Re

    Mase je ki ‘pade wa yi 

    Ko je asan nigbehin 

    F’oju anu wo ‘papo wa 

    K'a le ma pade titi.  Amin

English »

Update Hymn