HYMN 472

H.C 298 7s(FE 497) 
"Awon agutan mi ki yio segbe"
- John.10:28



1.  TIRE lailai I’awa se

     Baba, Olorun ife

     Je ka je Tire titi

     Laiyeyi, ati lailai.


2.  Tire lailai l’awa se 

     Ma toju wa l’aiye yi 

     Wo iye, ona, oto

     To wa si ilu orun.


3.  Tire lailai: Abukun

     L’awon t’o se ‘simi won

     Olugbala, Ore wa

     Gba ‘ja wa ja de opin.


4.  Tire lailai:- Jesu, pa

     Awon agutan Re mo 

    Labe iso rere Re

    Ni k’o pa gbogbo wa mo.


5.  Tire lailai-Aini wa

    Ni o je aniyan Re

    O ti f’ese wa ji wa

    To wa si ibugbe Re.  Amin 

English »

Update Hymn