HYMN 470


H.C 282 t.H.C 59 6. 8s (FE 495) 
“Alabukun li awan ti ko ri mi sugbon
ti nwon si gbagbo" - John.20:29



1.  Om’Olorun a ko ri O

     Gba t'o wa s'aiye iku yi 

     Awa ko ri ibugbe Re

     Ni Nasareti ti a gan

     Sugbon a gbagbo p’ese Re 

     Ti te ita re kakiri.


2.  A ko ri O lori igi 

     T'enia buburu kan O mo 

     A ko gbo Igbe Re, wipe 

    Dariji won, tor’ aimo won 

    Sibe, a gbagbo pe'ku Re 

    Mi aiye, o si m'orun su.


3.  A ko duro leti boji 

     Nibiti a gbe te O si

     A ko joko ‘na yara ni

     A ko ri O loju ona

    Sugbon a gbagbo p’angeli 

    Wipe ‘Iwo ti ji dide.


4.  A ko r’awon wonni t’o yan 

     Lati ri’goke r’orun Re

     Nwon ko fi iyanu woke

     Nwon si f 'eru dojubole

     Sugbo a gbagbo pe nwon ti ri O 

     Bi O ti ngoke lo s'orun.


5.  Iwo njoba l’oke loni

     ‘Wo si nbukun awon Tire 

     Imole ago Re ko tan

     Si aginju aiye wa yi 

     Sugbon, a gba oro re gbo 

     Jesu, Olurapada wa.  Amin

English »

Update Hymn