HYMN 468

t.9B 466 (FE 493)
"lwo ko gbodo ni Olorun miran” 
- Eks. 30:11



1.  OLORUN kan lo to k'a sin

     K'a si feran Re l‘afetan

     A ko gbodo bo orisa

     Nitori ohun asan ni.

Egbe:  K’a ranti pe lati ri igbala

           O to ka p’ofin mo 

           Ti Olorun ti so fun wa 

           Ti Olorun ti so fun wa.


2.  Kerubu pelu serafu 

     Feran omonikeji re 

     Ife ni awon angeli

     Ni nwon fi sin Baba loke. 

Egbe:  K’a ranti pe lati ri...


3.  Baba aladura mura 

     Lati pad’awon kerubu 

     Ade ogo yio je tire 

     T'omo araiye ko le gba. 

Egbe:  K’a ranti pe lati ri...


4.  Ileri to se fun Mose

     Ni ori oke Sion

     T’ope On yio wa pelu re 

     Lati ko wa de le Kenani.

Egbe:  K’a ranti pe lati ri...


5.  Agbagba merinlelogun 

     Ajuba oruko nla nyin 

     Ati eda ‘laye merin 

     Ke s'amin si adura wa. 

Egbe:  K’a ranti pe lati ri...


6.  Jehovah Jire Oba wa 

     Gbadura Egbe Kerubu 

     Jehovah Nissi Baba wa 

     Metalokan gbadura wa.

Egbe:  K’a ranti pe lati ri igbala

           O to ka p’ofin mo 

           Ti Olorun ti so fun wa 

           Ti Olorun ti so fun wa.  Amin

English »

Update Hymn