HYMN 467

H.C. 398 t.H.C 120 8s. 7s (FE 492) 
“Ohun ogo li a nso ni tire, ilu Olorun”
 - Ps. 87:3



1.  OHUN ago Re l’a nrohin 

     Sion, ti Olorun wa

     Oro enit’ a ko le ye 

     Se o ye fun ‘bugbe Re 

     L’ori apat’aiyeraiye 

     Kini le mi ‘simi re?

     A f’odi ‘gbala yi o ka 
   
     K’o le ma rin ota re.


2.  Wo! ipado omi iye 

     Nt’ife Olorun sun wa

     O to fun gbogbo omo Re 

     Eru aini ko si mo

     Tal’o le re ‘gba odo na 

     Ba nsan t’o le pongbe re 

     Or’ofe Olodumare

     Ki ye lat’irandiran.


3.  Ara Sion alabukun

     T’o f’eje Oluwa we

    Jesu ti nwon ti ngbekele 

    So won d'oba woli Re

    Sisa l’ohun afe aiye

    Pelu ago asan re

    Isura toto at'ayo 

    Kik'omo Sion l'o mo.  Amin

English »

Update Hymn