HYMN 455

K.117 t.H.C 320 C.M (FE 480)
"O si pe oruko ibe na ni Jehovah-Jire"
- Gen.22:14 1



1.  KO to k’awon mimo beru 

     Ki nwon so ‘reti nu

     ‘Gba nwon ko reti ‘ranwo Re, 

     Olugbala y’o de.

Egbe:  Jesu mbo (3) 

           Enyin Omo ogun, 

           E damure giri.


2.  Nigbati Abram mu obe 

     Olorun ni "Duro” 

     Agbo ti o wa lohun ni 

     Y‘o dipo omo na.

Egbe:  Jesu mbo...


3.  ‘Gba Jona ri sinu omi 

     Ko ro lati yo mo 

     Sugbon Olorun ran eje 

     To gbe lo s’ebute. 

Egbe:  Jesu mbo...


4.  B'iru ipa at'ife yi
 
     Ti po l'oro Re to 

     Emi ba ma k'aniyan mi 

     Le Oluwa lowo.

Egbe:  Jesu mbo...


5.  E duro de iranwo Re 

     B’o tile pe, duro

     B’ileri na tile fa ‘le

     Sugbon ko le pe de.

Egbe:  Jesu mbo (3) 

           Enyin Omo ogun, 

           E damure giri.  Amin

English »

Update Hymn