HYMN 452

H.C 451 8s 7s (FE 477) 
"Oluwa li Oluso-agutan mi, 
emi ki o se alaini" - PS. 23:1



1.  JESU l‘Olusagutan mi, 

     Ore eniti ki ye

     Ko s’ewu bi mo je Tire 

     T’O si je temi titi.


2.  Nib’odo omi iye nsan 

     Nibe I’onm‘okan mi lo 

     Nibiti oko tutu nhu 

     L'o nf’onje orun bo mi.


3.  Mo ti fi were sako lo 

     N’ife O si wa mi ri 

     L'ejika Re l'o gbe mi si 

     O f‘ayo mu mu wa le.


4.  Nko beru ojiji iku 

     B’Iwo ba wa lodo mi 

     Ogo Re ati Opa Re 

     Awon l’o ntu mi ninu.


5.  Iwo te tabili fun mi 

     Wo d’ororo sori mi

     A! ayo na ha ti po to! 

     Ti nt‘odo Re wa ba mi.


6.  Be lojo aiye mi gbogbo 

     Ore Re ki o ye lai 

     Olusagutan, ngo yin O 

     Ninu ile Re titi.  Amin

English »

Update Hymn