HYMN 446

H.C 280 10s (FE 470)
“Okan eniti o simi le O, Iwo o pa 
a mo li alafia" - Isa. 26:3



1.  ALAFIA, li aiye ese yi? 

     Eje Jesu nwipe, Alafia”


2.  Alafia ninu opo lala? 
 
     Lati se ife Jesu, ni ‘simi.


3.  Alafia, n’nu igbi ‘banuje? 

     L'aiya Jesu ni dake roro wa.


4.  Alafia, gb'ara wa wa l‘ajo? 

     Ni 'pamo Jesu, iberu ko si.


5.  Alafia, b'a ko tile m‘ola? 

     Sugbon a mo pe Jesu wa lailai.


6.  Alafia, nigb’akoko iku? 

     Olugbala wa ti segun iku?


7.  O to: jakadi aiye fere pin

     Jesu y'o pe wa s’orun alafia.  Amin

English »

Update Hymn