HYMN 444

H.C 2nd Ed. 279
t.H.C 579 10s. 11s (FE 468)
“Bi enyin ko tile ri nisiyi, sugbon enyin 
ngba a gbo" - I Peteru 1:8



1.  AIGBAGBO, bila temi l'Oluwa

     On o si dide fun igbala mi

     Ki nsa ma gbadura, On o se ranwo 

     Gba Krist’wa lodo mi ifoiya ko si.


2.  B’ona mi ba su, On l’o sa nto mi 

     Ki nsa gboran sa, On o si pese, 

     Bi iranlowo eda gbogbo saki 

     Oro t‘enu Re so y'o bori dandan.


3.  lfe t’o nfi han ko je ki nro pe 

     Y‘o fi mi sile ninu wahala

     Iranwo ti mo si nri lojojumo 

     O nki mi laiya pe, emi o la ja.


4.  Emi o se kun tori iponju

     Tabi irora? O ti so tele

     Mo m’oro Re p’awon ajogun ‘gbala 

     Nwon ko le s’aikoja larin wahala.


5.  Eda ko le so kikoro ago

     T’Olugbala mu, k’elese le ye

     Aiye Re tile buru ju temi lo 

     Jesu ha le jiya, k’emi si ma sa!


6.  Nje b’ohun gbogbo ti nsise ire 

     Adun n’ikoro, onje li ogun

    B’oni tile koro, sa ko ni pe mo 

    ‘Gbana orin ‘segun yio ti dun to!  Amin

English »

Update Hymn