HYMN 442

H.C. 281 C.M (FE 466) 
"Awon Aposteli si wi fun Oluwa pe,
Busi igbagbo wa" - Luku 17:5



1.  A ba le n’igbagbo aye 

     B’o ti wu k'ota po 

     Igbagbo ti ko je mira 

     Fun aini at’osi.


2.  Igbagbo ti ko je rahun

     L'abe ibawi Re 

     Sugbon ti nsimi l’Olorun

     Nigba ibanuje


3.  Igbagbo ti ntan siwaju
 
     Gbat' iji 'ponju de

     Ti ko si je siyemeji

     N'nu wahala gbogbo.


4.  Igbagbo ti ngb'ona toro

     Titi emi o pin

     Ti y'o si f'imole orun

     Tan akete iku.


5.  Jesu f’igbagbo yi fun mi 

     Nje b’o ti wu k‘o ri

     Lat'aiye yi lo ngo l’ayo 

     Ilu orun rere.  Amin

English »

Update Hymn