HYMN 441

7s 6s (FE 465) 
"Awon enia mi yio mo oruko mi"
-Isa.52:6
Tune: Ojo ayo l'eyi je



1.  GBOGBO enyin Onigbagbo 

     To wa lode aiye 

     Babalawo gbe ‘fa wa

     O tun d’Aladura.

Egbe:  E yi pada

           Ojo ‘dajo de tan

           E yi pada, e sunmo Olorun.


2.  Pupo abogi bo ‘pe 

     Fori bale f’Oba 

     Nwon si tun jeri Kristi 

     Niwaj’onigbagbo.

Egbe: E yi pada...


3.  Oro Olugbala se, 

     Lori gbogbo aiye 

     Wipe gbogbo ekun ni 

     Yio wole fun mi. 

Egbe: E yi pada...


4.  Sib’awon onigbagbo 

     Gb'ohun asan dani 

     T'o ni ohun ‘dile ni 

     Emi ko le s'aise. 

Egbe: E yi pada...


5.  ltiju pupo yio wa 

     F’awon onigbagbop 

     At'awon onimale 

     Gb'onifa ba wole. 

Egbe: E yi pada...


6.  Okunrin at’obinrin 

     T’o wa nin’Egbe yi 

     Ise po pupo l’oko 

     Tal‘awa yio ran lo. 

Egbe: E yi pada...


7.  O seun omo rere 

     L’ohun ‘kehin yio je 

     F'awon to s‘olotito 

     ‘Nu Egbe Kerubu. 

Egbe: E yi pada...


8.  E lo kuro lodo mi 

     Emi ko mo nyin ri 

     L’ohun ikehin yio je 

     F‘awon alaigbagbo. 

Egbe: E yi pada...


9.  Jehovah Jire Baba 

     Jowo pese fun wa 

     Jehovah Nisi Baba 

     Pa wa mo de opin.

Egbe:  E yi pada

           Ojo ‘dajo de tan

           E yi pada, e sunmo 

           Olorun.  Amin

English »

Update Hymn