HYMN 44

(FE 61) C.M.S 27, o.t H.C 16, L.M
“Ni ijo mefa ni iwo o sise" - Eks. 20:9



1.  OJO isimi Olorun

     Ojo ti o dara julo

     Ti Oluwa ti fun wa 

     K’awa ko simi ninu re.


2.  ljo mefa l‘O fi fun wa 

     K‘a fi se ise wa gbogbo 

     Sugbon ojo keje yato 

     Ojo 'simi Olorun ni.


3.  K'a fi ‘se asan wa,sile 

     Ti awa nse n’ijo mefa 

     Mimo ni ise ti oni

     Ti Olorun Oluwa wa.


4.  A pada de nisisyi 

     Ninu ile Olorun wa 

    Je k'a korin didun si i 

    Li owuro ojo oni.


5.  Ni kutukutu ‘jo keje

     Ni ojo isimi mimo 

     Je k'a jumo korin didun 

     Je k'a si jumo gbadura.  Amin

English »

Update Hymn