HYMN 439

(FE 463) 
Tune: Oluwa fise Ran Mi Alleluyah



1.  OLUWA l’oluso mi

     emi ki o s’alaini

     Jesu l‘osugo agutan omo Re

     O mu mi sun ni papa oko tutu to dara 

     O tu ara ati okan mi lara. 

Egbe:  Damuuso fun Baba

            Awa ma ridi jinle, Kabiyesi

            Messiah mimo jowo mase le

            mi Iodo Re

            Nipa ore‐ofe Re ki nle de 'be.


2.  Bi mo tile nkoja lo larin afonifoji 

     T‘o kun fun banuje at' opo ‘damu 
  
     Emi ki o si beru ohunkohun to le de 

     Tori Oluwa ogo wa pelu mi.

Egbe:  Damuuso fun Baba...


3.  Iwo fun mi li onje loju awon ota mi 

     O da ororo ‘fe Re simi lori

     Ire anu at‘ayo yo ma ba mi gbe titi 

     Ngo si ma yin O Oluwa titi lai. 

Egbe:  Damuuso fun Baba...


4.  Olorun aiyeraiye to da orun at‘aiye 
 
     Awa juba Re eleda alaye

     F‘anu Re lori awn eda owo Re laiye 

     F’abo to fi nbo wa ni ojo gbogbo. 

Egbe:  Damuuso fun Baba...


5.  A f'ogo f’oruko Re, 

     Jehovah mimo loke

     Jesu omo mimo to ra wa pada 

     A f'ogo f'Emi mimo to so 

    wa d‘eni iye
 
     Ogo f’ologo Metalokan lailai.

Egbe:  Damuuso fun Baba

            Awa ma ridi jinle, Kabiyesi

            Messiah mimo jowo mase le

            mi Iodo Re

            Nipa ore‐ofe Re ki nle de 'be.  Amin

English »

Update Hymn