HYMN 438

(FE 462)
"Ore mi Ii enyin ise" - John 15:14



1.  ORE bi Jesu ko si l’aiye yi 

     On nikan l'ore otito

     Ore aiye yi le ko wa sile 

     Sugbon Jesu ko je gbagbe mi. 

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!

           A! ko je gbagbe mi!

           Sugbon Jeru ko je gbagbe mi.


2.  Duro d‘Oluwa, ma siyemeji 

     Ohunkohun to wu ko le de 

     ‘Gbati o ro pin, 'ranwo Re yio de 

     Eni ‘yanu l'Oba Oluwa. 

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!...


3.  Enyin Alagba at’Aladura 

     Ati gbogbo Egbe Ojise 

     Onidajo mbo gongo yio so 

     Awawi kan ko si lojo na.

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!...


4.  Enyin Om’Egbe Akorin bile 

     Ati gbogbo Egbe Akorin 

     Olugbala mbo lati pin ere

     O daju pe ko je gbagbe mi. 

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!...


5.  Ojo mbo t’ao dan ‘gbagbo nyin wo 

     Kerubu on Serafu t’aiye

     Ina l'ao ft dan ‘gbagbo nyin wo 

     T’eni to ba jona padanu.

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!...


6.  Ogo fun Baba, Ogo fun Omo 

     Ogo si ni fun Emi Mimo

     Ao fi ogo fun Metalokan

     O daju pe ko je gbagbe mi.

Egbe:  A! ko je gbagbe mi!

           A! ko je gbagbe mi!

           Sugbon Jeru ko je 

           gbagbe mi.  Amin

English »

Update Hymn