HYMN 436

S.S. &S 610 (FE 560)
"Jesu wipe, e ma to mi lehin"
- Marku 1:17



1.  MO fi gbogbo re fun Jesu, 

     Patapata l’aiku ‘kan

     Ngo ma fe, ngo si gbekele 

     Ngo si ma ba gbe titi. 

Egbe:  Mo fi gbogbo re, Mo fi gbogbo re 

           Fun O, Olugbala mi, ni 

           Mo fi won sile.


2.  Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

     Mo si wole lese Re,

     Mo fi afe aiye sile

     Jesu, Jo gba mi wayi,

Egbe:  Mo fi gbogbo re...


3.  Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

     Jesu se mi ni Tire

     Jek’ Emi Mimo s’eleri 

     Pe, O si je t’emi na. 

Egbe:  Mo fi gbogbo re...


4.  Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

     Mo f’ara mi f'Oluwa

     F’ife at‘agbara kun mi 

     Si fun mi n’ibukun Re. 

Egbe:  Mo fi gbogbo re...


5.  Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

     Okan mi ngbona wayi

     A! ayo igbala kikun

    Ogo ni f’oruko Re. 

Egbe:  Mo fi gbogbo re...


6.  Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

     Mo f’ojo aiye mi fun 

     K’o ma so, k’o si ma to mi 

     K’o fi ‘nu mi se ‘bugbe. 

Egbe:  Mo fi gbogbo re...


7.  Kerubu pelu Serafu 

     Se Metalokan n’tire

     Fi Baba, Omo at’Emi 

     Se tire titi aiye.

Egbe:  Mo fi gbogbo re, Mo fi gbogbo re 

           Fun O, Olugbala mi, ni 

           Mo fi won sile.  Amin

English »

Update Hymn