HYMN 435

S.S 640 (FE 459)
"E fi Ogo fun Oruko Oluwa” - Ps. 96:8



1.  EMI ko wa oro aiye 

     O pese f’aini mi, 

     Sugbon ngo noga siwaju 

     F‘oju to mu hanhan

     Ki ngbekele O Oluwa 

     F‘ore-ofe ojojumo. 

Egbe:  Gbana l‘okan mi o korin 

            Labe agbelebu

            Nitori ‘simi dun l'ese Krist' 

            Gba mo fi ‘gbagbo re 'le

            Gba mo fi ‘gbagbo re 'le.


2.  Nki y’o nani ohun aiye

     To o nrogba yi mi ka 

     Sugbon ngo f ’ayo sa ‘pa mi, 

     Iyoku d’owo Re

     O daju p’ere didun wa, 

     F’awon to simi l’Oluwa. 

Egbe:  Gbana l‘okan mi o korin...


3.  Ng’ ki y’o sa f‘agbelebu mi, 

     Ohun t'o wu k’ o je

     Sugbon ki nsa le wa fun O 

     Ki nsa se ife Re

     Ki ng’ se‘ fe Re lojojumo

     Gba mba fi ‘gbagbo sunmole. 

Egbe:  Gbana l‘okan mi o korin...


4.  Gba mo ba pari ise mi 

     Ti mo koja odo 

     Oluwa jo jek’okan mi 

     Le ba O gbe titi

     Ki nko ‘hun ti mo nihin

     Bi ‘fe Re ti po si mi to.

Egbe:  Gbana l‘okan mi o korin 

            Labe agbelebu

            Nitori ‘simi dun l'ese Krist' 

            Gba mo fi ‘gbagbo re 'le

            Gba mo fi ‘gbagbo re 'le.  Amin

English »

Update Hymn