HYMN 433

(FE 457)



1.  OLUWA f‘ise ran mi, Alleluya

     Emi yio je ‘se na fun O

     O wa ninu oro Re, Alleluya

     Wo Jesu nikansoso k'o ye.

Egbe:  Wo k‘o ye ara mi ye
 
           Bojuwo Jesu k'o ye,

           Ise l'a toke wa ni Alleluya 

           E jek'a wo Jesu k’a si ye.


2.  Ise na kun fun ife, Alleluya 

     Fun enyin era ilu Eko, 

     Ise lat‘oke wa ni Alleluya 

     At’awon t’o wa n'ilu oke.

Egbe:  Wo k‘o ye ara mi ye...


3.  Gbogbo Egbe agbaiye, Alleluya 

     Jesu nke tantan wipe ma bo 

     Igbala l'ofe d’ode, Alleluya

     Jek‘ajuba Jesu k‘a si ye. 

Egbe:  Wo k‘o ye ara mi ye...


4.  Jesu Olugbala wa, Alleluya 

     A f'ogo f'oruko Mimo Re 

     Fun idasi wa loni, Alleluya 

     lyin fun Metalokan lailai. 

Egbe:  Wo k‘o ye ara mi ye...


5.  Kerubu on Serafu, Alleluya 

     E ja titi d’opin emi nyin; 

     K'a le gba ade iye, Alleluya 

     Lodo Baba loke lohun.

Egbe:  Wo k‘o ye ara mi ye
 
           Bojuwo Jesu k'o ye,

           Ise l'a toke wa ni Alleluya 

           E jek'a wo Jesu k’a si ye.  Amin

English »

Update Hymn