HYMN 432

H.C 272 10s (FE 456) 
"O ye ki enia ma gbadura nigba 
gbogbo, ati laise are" - Luku 18:1



1.  MA gbadura, Emi mbebe N’nu re 

     Fun gbogbo aini re igbagbogbo.


2.  Ma gbadura, labe eru ese 

     Adura nri eje Jesu ti nsan.


3.  Ma ghadura, b‘are tile mu O 

     Adura ngbe wa s'eba ‘te, Baba.


4.  Ma gbadura, n’nu wahala aiye, 

     Adura l'o nfun okan n‘isimi.


5.  Ma ghadura, b'ayo ba yi o ka

     Adura nlu harp, o nkorin Angel’


6.  Ma ghadura, b'awon t'o feran ku

     Adura mba won mu omi iye


7.  Gbogb'ohun aiye y'o b’ aiye koja

     Adura wa titi: ma gbadura.  Amin 

English »

Update Hymn