HYMN 431

Tune: C.M.S 491 H.C
215 C&F 3.Y.L.C 88 6s.5s (FE 455) 
“Maa wi nitori ti iranse re ngbo"
- 1Sam.3:9



1.  BA mi soro, Jesu 

     Bi mo ti duro

     Fi okan mi le ‘le 

     Ninu ireti.


2.  Ba mi soro Baba 

     Ni wakati yi

     Je ki nri oju Re 

     Nin‘olanla Re.


3.  Oro ti O ba so 

     'Oro iye ni 

     Onje orun

     Ma bo mi titi.


4.  Tire l’ohun gbogbo 

     Nki si se t'emi

     Ayo ni mo fi wi 

     Pe, Tire l'emi.


5.  Fun mi ni imo na 

     T'ise ogo Re

     Mu gbogbo ileri

     Re se s’ara mi.  Amin

English »

Update Hymn