HYMN 43

8.7.8.7 D



1.  GBOGBO‘ogun orun nro keke 

     Angeli mu harpu won

     Awon mimo nt‘ohun won se 

     Lati josin t‘o l’ogo

     Ojo ‘simi t'OIorun de 

     Ojo t'o l'ogo julo

     Orun kun fun iho ayo 

     A! b’isin won ti dun to.


2.  Jek'a pelu awon t‘orun 

     Yin Olorun Oba wa 

     Jek’a pa 'le okan wa mo 

     K'a f‘ohun mimo korin 

     Apere ni ti wa le je 

     T'isimi ti won loke

     Titi ao fi ri Oluwa 

     Ti a nsin l'ojukoju.


3.  K’o to d’igba na, e jeki

     A ma sin l’ojo keje

     K’a f‘aniyan wa s'apakan 

     K'a pe sinu ile Re 

     O ti pase k'a ma se be

     Y'o bukun ipejo wa 

     E jek‘a sin li aisaare 

     Ere re y'o je ti wa.  Amin

English »

Update Hymn