HYMN 425

C.M.S 536 H.C 386 L.M (FE 448)
"Nibiti eni meji, tabi meta ba ko ara 
won jo li oruko Mi, nibe Ii Emi o wa Ii 
arin won" - Matt. 18:20



1.  JESU, nib'eni Re pade

     Nibe, nwon r‘ite anu Re

     Nibe, nwon wa O, nwon ri O

     lbikibi n’ile owo.


2.  Ko s’ogiri t'o se O mo

     O gbe inu onirele

     Nwon mu O wa ‘bi nwon ba wa

     Gba nwon nlo le won mu O lo.


3.  Olus‘agutan eni Re

     So anu Re ‘gbani d'otun

     So adun oruko nla Re

     Fun okan ti nwa oju Re.


4.  Je k’a r‘ipa adua nihin

     Lati so ‘gbagbo di lile

     Lati gbe ife wa soke

     Lati gb’orun ka ‘waju wa.


5.  Oluwa,‘Wo wa nitosi

     N'apa Re de ‘ti Re sile

     Si orun sokale kankan 

     Se gbogbo okan ni Tire.  Amin

English »

Update Hymn