HYMN 424

C.S.M 537 T.C.H 51 L.M (FE 447) 
"Omo Olorun ye, o si li agbara" - Heb.4:12



1.  JE ki ilekun aitase

     Si fun ise wa, Oluwa 

     Ti o si ti ki o ti mo 

     Ilekun ‘wole oro re.


2.  F‘owo ina to ete won

     Ti nfi’ lana Re han aiye

     F'ife mimo si aiya won

     Ti Olorun at'enia.


3.  F'itara fun iranse Re,

     T’ohun kan ko le mu tutu

     Bi nwon si ti ntan oro Re

     Bukun imo at’ise won.


4.  Ran Emi Re lat'oke wa

     Ma je ki agbara Re pin

     Tit'irira o fi pari,

     Ti gbogbo ija o si tan.  Amin

English »

Update Hymn