HYMN 422

C.M.S 571 t.S. 86 C.M. (FE 445) 
"Eda ara mi ko pamo kuro lodo Re"
- Ps. 139:15



1.  TERUTERU t’iyanu ni 

     Olorun mi da mi 

     Gbogbo awon eya ara mi 

     Ise iyanu ni.


2.  Nigbat' a da mi n’ikoko 

     O ti mo ara mi

     Eya ara mi l'O si mo 

     Sa t’okan won ko si.


3.  Olorun, iro inu Re 

     Se ‘yebiye fun mi 

     Iye won poju iyanrin 

     Ti ko seni le ka.


4.  B’o ti mo eda mi bayi 

     Wadi okan temi

     Mu mi mo ona Re lailai 

     Si ma to ese mi.  Amin

English »

Update Hymn