HYMN 415

S.48 L.D.L.M (FE 438)
“Wakati adura" - Ise 3:1



1.  WAKATI adura didun!

     T‘o gbe mi lo kuro l'aiye 

     Lo'waju ite Baba mi

     Ki nso gbogbo edun mi fun

     Nigba ‘banuje at‘aro

     Adua l'abo fun okan mi

     Emi si bo lowo Esu

     'Gbati mo ba gb'adua didun

     Emi si bo lowo Esu

     'Gbati mo ba gb'adua didun. 


2.  Wakati adura didun!

     Iye re y’o gbe ebe mi

     Lo sod’Enit’ o se ‘leri 

     Lati bukun okan adua

     B’O ti ko mi, ki nwoju Re 

     Ki ngbekele, ki nsi gbagbo 

     Ngo ko gbogb’aniyan mi le 

     Ni akoko adua didun.


3.  Wakati adura didun!

     Jeki nma r’itunu re gba 

     Titi ngo fi d’oke Pisga

     T ngo r’ile mi l’okere 

     Ngo bo ago ara sile

     Ngo gba ere ainipekun

     Ngo korin bi mo ti nfo lo

     Odigbose! adua didun,

     Ngo korin bi mo ti nfo lo

     Odigbose! adua didun.  Amin

English »

Update Hymn