HYMN 414

(FE 437)
"Akanse orin fun adura awon aboyun, 
omo were ati awon ti nwoju Oluwa"
Tune: Jesu ni Balogun oko




1.  JESU lo ngbebi aboyun

     E mase jek' a foiya

     Olugbala wa ni Jesu

     E mase je k'a foiya.

Egbe:  E mase beru

           E kun fun ayo

           Nitori Jesu ni Oba wa

           B'o ti wu k'iji na leto

           Y’o da wa sile Iayo.


2.  Enyin aboyun Serafu 

     E kepe Jesu nikan

     K'e si gbeke nyin le pelu 

     Y'o da nyin sile l'ayo

Egbe:  E mase beru...


3.  Olugbala, ‘Wo ti ‘ya re 

     Ru O gba osu mesan 

     Ni bethlehem Judea 

     Layo ibi sokale.

Egbe:  E mase beru...


4.  Ki l’ohun ti mba nyin l‘eru 

     Enyin Omo ogun Kristi

     Gbati Jesu ti je tiwa

     Ayo ni yio je tiwa. 

Egbe:  E mase beru...


5.  Lowo, aje ati oso 

     Lowo ajakale arun

     Lowo lku, ekun, ose

     Jesu yio pa Tire mo. 

Egbe:  E mase beru...


6.  Metalokan Alagbara 

     Dabobo awon omo Re

     Lowo ota ati esu

     Jek’ awa k‘Alleluyah. 

Egbe:  E mase beru...


7.  Olorun to l’agan ninu 

     Y‘o gbo t’enyin ti ntoro

     B'O ti s‘ekun Hannah d‘erin

     Yo f’omo pa nyin l‘erin. 

Egbe:  E mase beru...


8.  Ogo ni fun Baba l‘oke 

     Ogo ni fun Omo Re

     Ogo ni fun Emi Mimo

     Metalokan l'ope ye.

Egbe:  E mase beru

           E kun fun ayo

           Nitori Jesu ni Oba wa

           B'o ti wu k'iji na leto

           Y’o da wa sile Iayo.  Amin

English »

Update Hymn