HYMN 41

C.M.S.39, H.C. 15, L.M (FE 58)
“Emi o tu Emi mi jade sara, 
gbogbo enia" - lse 2:17



1.  EMI Olorun alaye 

     N‘nu ekun ore-ofe Re, 

     Nibit‘ ese enia ti te 

     Sokale sori iran wa.


2.  F’ebun ahon, okan ife, 

     Fun wa lati soro ‘fe Re, 

     K‘ibukun at’agbara Re, 

     Ba l‘awon t'o ngbo oro na.


3.  K’okun kase ni bibo Re; 

     Ki darudapo di tito 

     F‘ilera f'okan ailera 

     Jeki anu bori ibinu.


4.  Emi Olorun, jo pese 

     Gbogbo aiye fun Oluwa;

     Mi si won b' afefe oro 

     K'okan okuta le soji.


5.  Baptis' gbogb' orile-ede

     Rohin ‘segun Jesu yika

     Yin Oruko Jesu logo

    Tit‘araiye yio jewo Re.  Amin

English »

Update Hymn