HYMN 408

H.C. 268 t.H.C. 239 C.M
’Ilana re li o ti nse orin mi, ni ile 
ati po mi” - Ps.119:54



1.  BABA orun, nin’oro Re

     Ni ogo orun ntan

     Titi lai l'a o ma yin O

     Fun Bibeli mimo.


2.  Opo ‘tunu wa ninu re

     Fun okan alare

     Gbogbo okan ti ongbe ngbe 

     Nri omi iye mu.


3.  Ninu re l’alafia wa 

     Ti Jesu ti fun wa

     lye ainipekun si wa

     N’nu re fun gbogbo wa.


4.  lba le ma je ayo mi 

     Lati ma ka titi

     Ki nma ri ogbon titun ko 

     N’nu re lojojumo.


5.  Oluwa Oluko orun 

     Mase jina si mi

     Ko mi lati fe oro re

     Ki nri Jesu nibe.  Amin

English »

Update Hymn