HYMN 404

H.C 133 C.M. (FE 427)
“Oluwa ise Re ti pio to!" - Ps. 104:24



1.  IWE kan wa ti kika re

     Ko soro fun enia

     Ogbon ti awon t’o ka nfe 

     Ni okan ti o mo.


2.  lse gbogbo t’Olorun se 

     L'oke n’ile, n'nu wa 

     Nwon j’okan ninu iwe na 

     Lati f’Olorun han.


3.  Imole osupa l’oke 

     Lat’ odo orun ni 

     Be l’ogo Ijo Olorun 

     T’odo Olorun wa.


4.  lwo ti O jeki a ri 

     Ohun t‘o dara yi

     Fun wa l‘okan lati wa O

     K'a ri O nibi gbogbo.  Amin

English »

Update Hymn