HYMN 402

H.C 601 8s 7s (FE 425)
"Nitori mi ati nitori ihinrere" - Marku 8:35



1.  ‘Tori Mi at’lhinrere 

     E lo so t‘irapada

     Awon onse Re nke Amin!

     Tire ni gbogbo ogo

     Nwon nso t'ibi, t’iya, t’iku 

     Ife etutu nla Re

     Nwon ka ohun aiye s’ofo 

     T' ajinde on 'joba Re.


2.  Gbo, gbo ipe ti Jubili

     O ndun yi gbogbo aiye ka 

     N’ile ati l'oju okun

     A ntan ihin igbala  

    Bi ojo na ti nsumole 

    T‘ogun si ngbona janjan

    Imole ila-orun na

    Y’o mo Iarin okunkun.


3.  Siwaju ati siwaju

     Lao ma gbo Halleluya 

     Ijo ajagun y'o ma yo 

     Pe l’awon oku mimo

     A fo aso won n’nu eje 

     Duru wura won si ndun 

     Aiye at'orun d’ohun po 

     Nwon nko orin isegun.


4.  O de, Enit’ a nw’ona Re 

     Eni ikehin na de, 

     lmmanueli t'o d’ade 

     Oluwa awon mimo 

     lye, Imole at'Ife 

     Metalokan titi lai

     Tire ni ite Olorun

     Ati t’Odo-aguntan.  Amin

English »

Update Hymn