HYMN 401

C.M (FE 424)
"Emi o tu Emi mi jade si ara enia
gbogbo" - Joeli 2:28



1.  EMI Mimo, mi s'okan wa, 

     K'a mo agbara Re

     Orisun emi ‘sotele 

     T‘imole at'ife.


2.  Emi Mimo, l'agbara Re 

     L’awon woli sise

     lwo l’o nfi oto han wa 

     Ninu iwe mimo.


3.  Adaba orun, na ‘ye Re 

     Bo okun eda wa

     Jeki mole Re tan sori 

     Emi aisoto wa.


4.  A o mo Olorun daju 

     B’lwo ba mbe n‘nu wa 

     A o mo ‘jinle ife mimo 

     Pelu awon Tire.  Amin

English »

Update Hymn