HYMN 40

C.M.S 36, O.t.H.C. 16, L.M (FE 57)
"Awon Ii emi o si mu wa si oke mimo 
mi, emi o si mu inu won dun
ninu ile adura mi" - Isa. 56:7


1.  AYO l'ojo ‘simi fun mi 

     Ati agogo at'iwasu

    Gbat a ba mi n'nu 'banuje 

     Awon l'o nmu inu mi dun.


2.  Ayo si ni wakati na,

     Ti mo lo n'nu agbala Re, 

     Lati mo adun adura 

     Lati gba manna oro Re.


3.  Ayo ni idahun ‘Amin‘

    To gba gbogbo ile na kan, 

    Lekokan l'o ndun t‘o nrole 

    O nkoja lo s'odo Baba.


4.  B’aiye fe f'agbara de mi

     Mo ise ijo mefa re;

     Oluwa, jo tu ide na, 

     K'O so okan mi d’ominira.  Amin

English »

Update Hymn