HYMN 399

(FE 422)
H.C. 2nd Ed 263 t.H.C 8s. 7s 6s
'Oro re ni fitila fun ese mi" - Ps. 119:105



1.  IWO Oro Olorun 

     Ogbon at'oke wa

     Oto ti ki yipada 

     Imole aiye wa

     Awa yin O fun ‘mole 

     T‘inu lwe mimo 

     Fitila fun ese wa

     Ti ntan titi aiye.


2.  Oluwa l’o f’ebun yi 

     Fun ljo Re l’aiye

     A ngbe ‘mole na soke 

     Lati tan y’aiye ka

     Apoti wura n’ise 

     O kun fun Otito 

     Aworan kristi si ni 

     Oro iye toto.


3.  O nfe lele b’asia

     T’a ta loju ogun

     O ntan b’ina alore

     Si okunkun aiye 

     Amona enia ni

     Ni wahala gbogbo 

     Nin’arin omi aiye
 
     O mo wa sodo Kristi.


4.  Olugbala, se ‘jo Re 

     Ni fitila wura

     Lati tan imole Re 

     B’aiye igbani

     Ko awon ti o sako

     Lati lo ‘mole yi

     Tit‘okun aiye y’o pin

     Ti nwon o r’oju Re.  Amin

English »

Update Hymn