HYMN 397

(FE 420) 119 2nd Pt t.H.C 400 C.M
"Nipa ewo Ii odomokunrin yio fi mu 
ona Re mo? Nipa ikiyesi gegebi oro re"
 - Ps. 119:9



1.  BAWO ni awon ewe wa 

     Y‘o ti ma sora won?

     Bikose ‘nipa kiyesi 

     Gegebi oro Re.


2.  Gba oro na wo ‘nu okan 

     A tan imole ka

     Oro na ko ope l‘ogbon 

     At‘imo Olorun.


3.  Orun ni, imole wa ni 

     Amona wa l'osan 

     Fitila ti nfonahan wa 

     Ninu ewu oru.


4.  Oro Re, oto ni titi 

     Mimo ni gbogbo re 

     Amona wa l’ojo ewe 

     Opa l’ojo ogbo.  Amin

English »

Update Hymn