HYMN 394

t.H 577 6s 8s (FE 417)
"Nwon si fi ogo, ati ola, ati ope, fun 
eniti o joko lori ite" - Ifi 4:9



1.  MO f’iyin ailopin

     Fun Olorun baba 

     Fun ore aiye mi 

      At'ireti t’orun

     O ran Omo Re ayanfe 

     Lati ku fun ese aiye.


2.  Mo f'iyin ailopin 

     Fun Olorun Omo 

     T'O f‘eje Re we wa 

     Kuro ninu egbe 

     Nisisiyi O wa l'Oba 

     O nri eso irora Re.


3.  Mo f‘iyin ailopin 

     Fun Olorun Emi 

     Eni f ’agbara Re 

     So elese d’aye

     O pari ise igbala 

     O si fi ayo kun okan.


4.  Mo f’ola ailopin

     Fun Olodumare

     Wo Ologo meta

     Sugbon okansoso 

     B’O ti ju imo wa lo ni,

     A o ma f’igbagbo yin O.  Amin

English »

Update Hymn