HYMN 387

H.C 261 8.6.8.4 (FE 410)
"Emi o si bere Iowo Baba, on o si fun 
nyin li Olutunu miran, ki o le ma 
bo nyin gbe titi" - John 14:16



1.  OLURAPADA wa k’On to

     Dagbere ikehin
  
     O fi Olutunu fun ni 

     Ti mba wa gbe.


2.  O wa ni awo adaba 

     O na iye bo wa

     O tan ‘fe on alafia 

     Sori aiye.


3.  O de, o mu ‘wa-rere wa, 

     Alejo Olore,

     Gbat' o ba r'okan irele 

     Lati ma gbe.


4.  Tire l'ohun jeje t’a ngbo 

     Ohun kelekele

     Ti ngbaniwi, ti nl’eru lo 

     Ti nso t‘orun.


5.  Gbogho iwa‐rere t‘a nhu 

     Gbogbo isegun wa 

     Gbogbo ero iwa-mimo 

     Tire ni won.


6.  Emi Mimo Olutunu 

     F'iyonu be wa wo

     Jo, s’okan wa n’ibugbe Re 

     K‘o ye fun O.  Amin

English »

Update Hymn