HYMN 384

(FE 406)
C.M.S 279 H.C 262 t. A & M
470 7s 6s
“Emi o dabi iri si Israel" - Hos. 14:5



1.  EMI ‘bukun ti a nsin 

     Pelu baba at'oro 

     Olorun aiyeraiye 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


2.  Emi Mimo ‘Daba orun 

     Irti ri nse lat‘oke

     Emi ‘ye at’ina fe 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


3.  lsun ipa at’imo 

     Ogbon at'iwa mimo 

     Oye, imoran, eru 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


4.  lsun ife, alafia

     Suru, ibisi ‘gbagbo 

     Reti, ayo ti ki tan 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


5.  Emi afonahan ni 

     Emi ti nmu ‘mole wa 

     Emi agbara gbogbo 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


6.  ‘Wo t'o mu Wundia bi, 

     Eni t'orun t'aiye mbo 

     T'a ran lati tun wa bi 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


7.  ‘Wo ti Jesu t'oke ran

     Wa tu enia Re ninu

     Ki nwon ma ba nikan wa, 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


8.  Wo t’o nf'ore kun ljo 

     T’o nfi ife Baba han 

     T'O nmu k‘o ma ri Jesu 

     Emi Mimo, gbo tiwa.


9.  F‘ebun meje Re fun ni 

     Ogbon lati m'Olorun 

     lpa lati ko ota

     Emi Mimo, gbo tiwa.


10.  Pa ese run lokan wa, 

      To ife wa si ona

      Gba ba nse O, mu suru 

      Emi Mimo, gbo tiwa.


11.  Gbe wa dide b'a subu 

       Ati nigba idanwo

      Sa pe wa pada pele

      Emi Mimo, gbo tiwa.


12.  Wa, k'O mu ailera le 

       F'igboiya fun alare 

       Ko wa l’oro t'a o so 

       Emi Mimo, gbo tiwa.


13.  Wa ran okan wa lowo 

       Lati mo otito Re

       Ki‘ fe wa Ie ma gbona 

       Emi Mimo, gbo tiwa.


14.  Pa wa mo l‘ona toro 

       Ba wa wi nigb’a nsako 

       Ba wa bebe l’adura 

       Emi Mimo, gbo tiwa.


15.  Eni Mimo Olufe

       Wa gbe inu okan wa 

       Ma fi wa sile titi 

       Emi Mimo, gbo tiwa.  Amin

English »

Update Hymn