HYMN 383

H.C 6s 8s (FE 405)
"Emi Olorun si nrababa loju omi"
 - Gen. 1:2




1.  EMI Eleda nipa Re

     L‘a f‘ipile aiye sole

     Masai be gbogbo okan wo, 

     Fi ayo re si okan wa

     Yo wa nin‘ese at’egbe

     K'o fi wa se ibugbe Re.


2.  Orisun imole ni O

     Ti Baba ti se ileri

     lwo Ina mimo orun

     Fi ‘fe orun kun okan wa 

     Jo tu ororo mimo Re 

     Sori wa bi a ti nkorin.


3.  Da opo ore-ofe Re 

     Lat’orun sori gbogbo wa 

     Je k'a gba otito Re gbo 

     K'a si ma sa ro l'okan wa 

     F’ara Re han wa k’a le ri 

     Baba at‘Omo ninu Re.


4.  K‘a fi ola ati iyin

     Fun baba Olodumare

     K'a yin oko Jesu logo 

     Enit’o ku lati gba wa 

     Iyin bakanna ni fun O 

     Parakliti Aiyeraiye.  Amin

English »

Update Hymn