HYMN 382

H.C 250 t.H.C 16 L.M (FE 404) 
"Nitori aiye yio kun fun imo Oluwa 
bi omi ti bo okiun“ - Isa. 11:9



1.  EMI anu, oto, ife

     Ran aghara Re t‘oke wa 

     Mu iyanu ojo oni

     De opin akoko gbogbo.


2.  Ki gbogbo orile ede 

     Ko orin ogo Olorun

     Ki a si ko gbogbo aiye 

     N'ise Olurapada wa.


3.  Olutunu at'Amona 

     Joha ijo enia Re

     K'araiye mo ibukun Re 

     Emi anu, oto, ife.  Amin

English »

Update Hymn