HYMN 381

t.H.C 254 L.M (FE 402)
"Ko mi ni wa, ati imo rere" - Ps. 119:66



1.  ADABA orun sokale 

     Gbe wa lo l’apa iye Re

     Ki o si gbe a wa ga soke 

     Ju gbogbo ohun aiye lo.


2.  Awa iba le ri ite 

     Olodumare Baba wa 

     Olugbala joko nibe

     O gunwa l’awo bi tiwa.


3.  Egbe mimo duro yi ka

     lte Agbara wole fun 

     Olorun han ninu ara

     O si tan ogo yi won ka.


4.  Oluwa, akoko wo ni

     Emi o de bugbe won wole

     T'emi o ma ba won wole

     Ki nma sin O, ki nma korin?  Amin

English »

Update Hymn