HYMN 378

(FE 399)
Tune: E ma te siwaju serafu mimo



1.  EMI orun sokale

     Wa gbe ‘nu ile yi

     Ati eda alaye merin t‘o ngbe 

     orun Sokale wa l'agbara nyin

     Lat‘ oke mimo

     Ki adua aiyeraiye le wa

     s'aiye wa,

     E wa josin, e wa josin

     ninu ile yi

     Ki gbogbo ‘dawole wa le 

     yori si rere.


2.  Ki ase to sokale fun Baba nla wa,

     Solomon n’n adura re ni iyasimimo

     Ile Olorun aiyeraiye ti Jerusalemu

     Ni origun mererin to wa laiye yi

     Le wa dahun s'adura wa ninu ile yi 

     B'O ti dahun si Baba

     nla wa Solomon.


3.  Baba orun, Olore, juba wa ninu ile yi

     Awa omo Re tun de wa bere lowo Re,

    Omo ko san, omi ‘ponju omi ko ri Re,

    Omi nfe 'bukun omi ko le yin O l’ogo

    Jowo fun wa, jowo fun wa ni ibere,

    K‘ adura wa ‘gbagbogbo le yori si idahun.


4.  F’awon asiwaju l’ore-ofe kikun;

     B'O ti f'awon ti igbani l’aginju aiye yi 

     Nwon sise li oruko Re,

     nwon gb’ade ogo 

     F'awon na l’Emi Mimo lati gbade ogo; 

     Baba njiyin, iya njiyin, Aposteli nyin;

     Ati awon Efanjetist at’ Olus’agutan.


5.  K’ibukun ore-ofe kari gbogbo ljo,

     Lati agba titi d'ewe ati awon Oloye;

     Mary, Martyr. Ayab’ Esther 

     Awon Oluranlowo iya at‘

     awon to tun mbo 

     Baba nla ati f'ogo Om‘ogun ‘gbala 

     Ki‘ bukun Olodumare 

     Wa lori akorin.  Amin

English »

Update Hymn