HYMN 372

C.M.S 420 H.C 578 
(7.7.8.7.D) (FE 394)
"Ninu iponju Ii awa o fi de ijoba 
Orun" - Ise 14:22



1.  OLORI Ijo t'orun 

     L'ayo l’a wole fun O 

     K'O to de, Ijo t'aiye 

     Y'o ma korin bi t'orun 

     A gbe okan wa s'oke 

     Ni ‘reti t'o ni 'bukun 

     Awa kigbe, awa f’iyin 

     F’Olorun igbala wa.


2.  Gbat’ a wa ninu iponju 

     T‘a nkoja ninu ina 

     Orin ife l’awa o ko

     Ti o nmu wa sunmoO 

     Awa sope, a si yo

    Ninu ojurere Re

    lfe t'o so wa di Tire 

    Y'o se wa ni Tire lai.


3.  lwo mu awon enia Re 

     Koja isan idanwo 

     “Tori O wa nitosi 

     Aiye, ese, at’esu 

     Kojuja si wa lasan

     L’ agbara Re, a o segun 

     A o si ko orin Mose.


4.  Awa f'igbagbo r‘ogo 

     T’O tun nfe fi wa si 

     A kegan aiye ‘tori 

     Ere nla iwaju wa

     Bi O ba si ka wa ye

     Awa pelu Stefen t'o ku 

     Y‘o ri O bi O ti duro

     Lati pe wa lo s‘orun.  Amin

English »

Update Hymn