HYMN 366

H.C 242 6s (FE 388)
"Ninu ile Baba mi, opolopo 
ibugbe lo wa" - John 14:2



1.  ILE bukun kan wa 

     Lehin aiye wa yi

     Wahala, irora 

     At'ekun ki de ‘be 

     lgbagbo y'o dopin 

     Ao de 'reti l‘ade 

     Imole ailopin

     Ni gbogbo ibe je.


2.  Ile kan si tun mbe 

     Ile alafia

     Awon Angel rere 

     Nkorin n‘nu re lailai 

     Y‘ite ogo Re ka 

     L‘awon egbe mimo 

     Nwole nwon nteriba 

     F'Eni Metalokan.


3.  Ayo won ti po to! 

     Awon to ri Jesu 

     Nibit’o gbe gunwa 

     T‘a si nfi ogo fun 

     Nwon nkorin iyin Re

     At t’ isegun Re

     Nwon ko dekun rohin 

     Ohun nla t'o ti se.


4.  W'Oke, enyin mimo 

     E le iberu lo

     Ona hiha kanna 

     L’Olugbala ti gba

     E fi suru duro

     Fun igba die sa

     Terin-terin l’On o

     Fi gba nyin sodo Re.  Amin

English »

Update Hymn